John 13:21-30

21 aNígbà tí Jesu ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”

22Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń ṣiyèméjì ti ẹni tí ó wí. 23 bǸjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn. 24Nítorí náà ni Simoni Peteru ṣàpẹẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.”

25Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?”

26 cNítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ.

Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.”
28Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. 29 dNítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà. 30 eNígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà àkókò náà si jẹ òru.

Copyright information for YorBMYO